Hymn 279 – HOSANNA! e korin soke | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "HOSANNA! e korin soke" (C&S Hymn #279, Yoruba). 1. HOSANNA! ẹ kọrin soke, S'Ọmọ nla Dafidi, Pẹlu Kerub ati Seraf, K'a…

Hymn 279 – HOSANNA! e korin soke | C&S Yoruba Hymnary
1. HOSANNA! ẹ kọrin soke, S'Ọmọ nla Dafidi, Pẹlu Kerub ati Seraf, K'a yin Ọm-Ọlọrun. 2. Hosanna! eyi na nikan, L'ahọn wa le ma kọ, Iwọ ki o kẹgan ewe, Ti ń kọrin iyin Rẹ. 3. Hosanna! Alufa Ọba, Ẹbun Rẹ ti pọ to! Ẹjẹ Rẹ lo jẹ iye wa, Ọrọ Rẹ ni Ounjẹ wa. 4. Hosanna! Baba, awa mu Ọrẹ wa wa fun Ọ, Ki se wura oun ojia, Bikose ọkan wa. 5. Hosanna! Jesu, lẹkan ri, O yin awọn ewe; Saanu fun wa si f'eti si, Orin awa ewe. 6. Jesu, b'O ba ra wa pada, T'a si wọ 'jọba Rẹ; A o fi harpu wura kọ, Hosanna titi lai. AMIN

Hymn 279 – HOSANNA! e korin soke | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia