Hymn 277 – KRIST', ki 'joba Re de | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "KRIST', ki 'joba Re de" (C&S Hymn #277, Yoruba). 1. KRIST', ki 'jọba Rẹ de, Ki asẹ Rẹ bẹrẹ; F'ọpa-irin Rẹ fọ, Gbogbo…
1. KRIST', ki 'jọba Rẹ de, Ki asẹ Rẹ bẹrẹ; F'ọpa-irin Rẹ fọ, Gbogbo ipa ẹsẹ. 2. Ijọba ifẹ da, Ati t'alafia? Gba wo ni irira, Yoo tan bi t'ọrun? 3. Akoko naa ha da, T'ọtẹ yoo pari, Ika at'irẹjẹ, Pẹlu ifẹkufẹ? 4. Oluwa jọ, dide, Wa n'nu agbara Rẹ: Fi ayọ fun awa, Ti o n s'aferi Rẹ. 5. Ẹda ń gan ookọ Rẹ, Koko ń jẹ agbo Rẹ; Iwa 'tiju pupọ, Nfihan pe'fẹ tutu. 6. Okun bolẹ sibẹ, Ni ilẹ Keferi; Dide 'Rawọ oorọ, Dide, mase wọ mọ. AMIN
Hymn 277 – KRIST', ki 'joba Re de | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia