Hymn 027 – GBOGBO eyin araye | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "GBOGBO eyin araye" (C&S Hymn #027, Yoruba). 1. GBOGBO ẹyin ar'ayé To mb'ọjọ 'sinmi jẹ At'ẹyin alaigbọran Ti mb'ọjọ…
1. GBOGBO ẹyin ar'ayé To mb'ọjọ 'sinmi jẹ At'ẹyin alaigbọran Ti mb'ọjọ 'sinmi jẹ, Oluwa ran wa si yin Gẹgẹ b'alore Rẹ, Lati kede fun arayé P'Oluwa mbọ Kankan. Ẹyin Ẹgbẹ Kérúbù Ẹ mase jafara Ẹyin Ẹgbẹ Séráfù Ẹ d'amure giri. 2. Oluwa binu s'ayé Ẹda ko kiyesi Awọn t'o ti ni lọwọ, Wọn dẹni ti ko ni Ọdẹ 'Badan wa kede Ọrọ t'Angẹli sọ, Sugbọn kaka k'a yi pada A ń ri sinu ẹsẹ. 3. Keferi ẹ yi pada At'ẹyin Imale At'awọn Onigbagbọ T'o jẹbi ọrọ naa, Ẹ wa ka jọ gbadura, K'a bẹ Baba Mimọ, K'a tẹriba niwaju Rẹ, Yoo dariji wa. 4. Alanu ni Oluwa Eleti gb'aroye, Bi a ba yipada si Y'o yipada si wa, Ka p'ọjọ Oluwa mọ, Gẹgẹ bi asẹ Rẹ, Y'o si ferese Rẹ l'ọrun Igba rere yoo de. 5. Njẹ t'a ba si pe wa Lati f'ayé silẹ, T'a rekọja odo naa, Odo tutu iku, Ọlọrun Ẹlẹda wa Ma jẹ k'oju ti wa Mu wa d'ọrun Alafia K'a ba Ọ gbe titi AMIN
Hymn 027 – GBOGBO eyin araye | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia