Hymn 026 – GBOGBO ara aye | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "GBOGBO ara aye" (C&S Hymn #026, Yoruba). 1. GBOGBO ara ayé T'o wa ninu ẹsẹ, T'o n b'ọjọ 'sinmi jẹ, Oluwa ń ke si yin.…

Hymn 026 – GBOGBO ara aye | C&S Yoruba Hymnary
1. GBOGBO ara ayé T'o wa ninu ẹsẹ, T'o n b'ọjọ 'sinmi jẹ, Oluwa ń ke si yin. Ẹgbẹ Kérúbù, Séráfù Sọ farayé p'Oluwa mbọ (2) 2. Ẹ damure giri, Kérúbù, Séráfù, Ẹ funpe na kikan, Nipa t'ọjọ 'sinmi. 3. Ẹyin Onigbagbọ, L'awọn Imale ń wo, At'awọn Keferi, Nipa t'ọjọ 'sinmi. 4. E mura lati ba, Oluwa yin laja Mase f'aye silẹ F'esu lati mi yin 5. Tọrọ ida Ẹmi, Lọwọ Ọlọrun rẹ, Pẹlu bata irin Lati t'esu mọlẹ. 6. Oluwa fun wa se, K'a p'ọjọ mimọ mọ, Ka le ri igbala, Nikẹhin ọjọ wa. AMIN

Hymn 026 – GBOGBO ara aye | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia