Hymn 268 – WO ti n pafo ninu ese | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "WO ti n pafo ninu ese" (C&S Hymn #268, Yoruba). 1. 'WỌ ti n pafọ ninu ẹsẹ, Kristi n pe ọ wa sọdọ Rẹ, O ti sọ ẹru ẹsẹ…
1. 'WỌ ti n pafọ ninu ẹsẹ, Kristi n pe ọ wa sọdọ Rẹ, O ti sọ ẹru ẹsẹ rẹ, Wa sinu agbo Jesu. Kristi n pe ọ wa sọdọ Rẹ Oun l'O ni igbala kikun, Jesu n duro O n reti rẹ, 'Wọ yoo ha kọ ipe Rẹ? 2. Olugbala wa s'aye yi, Lati wa ra ọ pada, Lọwọ ẹsẹ ati arun, Igbala wo lo to yii? 3. Bo ti wu k'ẹsẹ rẹ pọ to, Kristi n fẹ sọ di mimọ, O ti pari 'sẹ gbala yi, O ku sọwọ rẹ, ma bọ. 4. Kristi n pe ọ lati ronu, Aye mbẹ sibẹ fun ọ, Wa, mase kiri 'nu ẹsẹ, Aye ko lere fun ọ. 5. B'aye at' esu n de si ọ, Ti 'pọnju bo ọ mọlẹ, Wa si abẹ abo Kristi, Nibẹ a o ri isinmi. AMIN
Hymn 268 – WO ti n pafo ninu ese | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia