Hymn 247 – NIGBA wen kehin si Sioni | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "NIGBA wen kehin si Sioni" (C&S Hymn #247, Yoruba). 1. NIGBA wọn kẹhin si Sioni, A! ọpọ n‘iye wọn; Mo sẹ b‘Olugbala wi…
1. NIGBA wọn kẹhin si Sioni, A! ọpọ n‘iye wọn; Mo sẹ b‘Olugbala wi pe, Wọ fẹ kọ mi pẹlu? 2. T‘emi t‘ọkan b‘iru eyi, A fi b‘O di mi mu; N ko le se ki n ma fa sẹhin, K‘emi si dabi wọn. 3. Mo mọ, Iwọ l‘o l‘agbara, Lati gba otosi; Odọ tani emi o lọ? Bi mo kẹhin si Ọ? 4. O da mi loju papa pe, Iwọ ni Kristi na! Ẹni t'o ni ẹmi iye, Nipa ti ẹjẹ Rẹ. 5. Ohun Rẹ f'isinmi fun mi, O si l'ẹru mi lọ; Ifẹ Rẹ lo le mu mi yọ, O si to f'ọkan mi. 6. Bi 'bere yi ti dun mi to, "Pe emi o lọ bi?" Oluwa, ni 'gbẹkẹle Rẹ, Mo dahun pe "Bẹkọ". AMIN
Hymn 247 – NIGBA wen kehin si Sioni | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia