Hymn 234 – OLUWA at'igbala wa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OLUWA at'igbala wa" (C&S Hymn #234, Yoruba). 1. OLUWA at'igbala wa, Amọna at'agbara wa, L'o ko wa jọ l'alẹ oni, Jẹ k'a…
1. OLUWA at'igbala wa, Amọna at'agbara wa, L'o ko wa jọ l'alẹ oni, Jẹ k'a gbe Ebeneseri ro; Ọdun t'a ti la kọja yi, Ni Oun f'ore Rẹ de lade, Ọtun l'anu Rẹ l'Owurọ; Njẹ ki ọpẹ wa ma pọ si! 2. Jesu t'o joko lor' itẹ; L'a fi Halleluyah wa fun; Nitori Rẹ nikansoso, L'a da wa si lati kọrin, Ran wa lọwọ lati kanu, Ẹsẹ ọdun t'o ti kọja; Fun ni k'a lo eyi ti mbọ; S'iyin Rẹ ju ọdun t'o lọ. AMIN
Hymn 234 – OLUWA at'igbala wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia