Hymn 232 – OLORUN Betel, eni ti | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLORUN Betel, eni ti" (C&S Hymn #232, Yoruba). 1. ỌLỌRUN Betel, ẹni ti, O mbọ awọn Tirẹ; Ẹni t'o mu baba wa la, Ọjọ…

Hymn 232 – OLORUN Betel, eni ti | C&S Yoruba Hymnary
1. ỌLỌRUN Betel, ẹni ti, O mbọ awọn Tirẹ; Ẹni t'o mu baba wa la, Ọjọ ayé wọn ja. 2. A mu ẹjẹ, at'ẹbẹ wa, Wa iwaju 'tẹ Rẹ, Ọlọrun awọn baba wa, Ma jẹ Ọlọrun wa. 3. Ninu idamu ayé yi, Ma tọju ipa wa; Fun wa ni Ounjẹ ojọ wa, At' asọ t'o yẹ wa. 4 Na ojiji 'yẹ Rẹ bo wa, Tit'ajo wa o pin, At' ni 'bugbe Baba wa, Ọkan wa o sinmi. 5 Iru ibukun bi eyi, L'a n bere lọwọ Rẹ; Iwọ o jẹ Ọlọrun wa, A t' ipin wa lailai. AMIN

Hymn 232 – OLORUN Betel, eni ti | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia