Hymn 205 – AKOKO to Kesari pase | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "AKOKO to Kesari pase" (C&S Hymn #205, Yoruba). 1. AKOKO to Kesari pasẹ Lati kọ orukọ sinu iwe, Maria ati Joseph goke,…

Hymn 205 – AKOKO to Kesari pase | C&S Yoruba Hymnary
1. AKOKO to Kesari pasẹ Lati kọ orukọ sinu iwe, Maria ati Joseph goke, Lati lọ si Betlehemu Judea. Iho Ayo Halleluya, A bi Olugbala fun wa. 2. Sugbọn ko s'aye fun wọn n'ile ero, Wọn ni lati wọ si ibujẹ-ẹran, Ko si Igbala nibi giga, Bikose n'ibi ti irẹlẹ gbe wa. 3. Ohun elo ailera l'Ọlọrun ń lo, Lati 'sọ igbala di kikun; Igbala ko si n'ibi igberaga, Lọdọ otosi ni Jesu gbe layé. 4. Awọn Ap'ẹja ni Jesu yan, Lati wasu ihin igbala fun ẹda; Ẹkọ nlanla ni eyi je f'ẹda, Pe ka ma kẹgan Isẹ Ọlọrun, 5. Akoko to, a bi Jesu, Emmanuẹli Kristi wa: Ọmọ Alade Alafia, Kiniun Judah Ọmọ Maria. 6. Irawọ Alafia yọ, Lati tọka Keferi s'ọdọ Ọlọrun; Bẹ la da Ẹgbẹ Séráfù silẹ, Lati f'ọna Igbala han f'ẹda. 7. Amoye mẹta ti ila orun wa, Wọn wa mu ase Olodumare se; Asọtẹlẹ nla ki la mọ eyi si, Wọn mu Wura, Turari oun Ojia wa. 8. Wọn juba Jesu ọmọ ta bi, Ọba Kérúbù ati Séráfù; Iho Ayọ, K'ẹda gbogbo gberin; Ẹ f'ogo fun Baba wa loke ọrun. Iho Ayọ Halleluya, A bi Olugbala fun wa. AMIN

Hymn 205 – AKOKO to Kesari pase | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia