Hymn 196 – Eyin Kerubu ati Serafu | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Eyin Kerubu ati Serafu" (C&S Hymn #196, Yoruba). 1. Ẹyin Kérúbù ati Séráfù; Ko gbogbo afẹ ayé yi silẹ, K'o rọ mọ ọkọ…
1. Ẹyin Kérúbù ati Séráfù; Ko gbogbo afẹ ayé yi silẹ, K'o rọ mọ ọkọ 'gbala yi, Ti Ọlọrun gbe kalẹ. Kọ si gbogbo ayé lati wa sin Oluwa, Nitori akoko si mbẹ f'ẹda, Ọjọ Oluwa si mbọ bi ole l'oru, Oluwa jọ gba wa la. 2. Ohun iyanu ń se, ẹ ko mi 'ra Ariran ń sọ adura ń gba Awọn Woli ń sisẹ t'a ń ri, Ọjọ Oluwa de tan. 3. Gbogbo ẹda igun mẹrin ayé, Ẹ wa wọ ọkọ 'gbala yi, Ti Mẹtalọkan gbe kalẹ, Lati gba gbogbo wa la. AMIN
Hymn 196 – Eyin Kerubu ati Serafu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia