Hymn 156 – SI O Olutunu orun | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "SI O Olutunu orun" (C&S Hymn #156, Yoruba). 1. SI Ọ Olutunu ọrun, Fun oore at'agbara Rẹ, A ń kọ Alleluya. 2. Si Ọ, ifẹ…
1. SI Ọ Olutunu ọrun, Fun oore at'agbara Rẹ, A ń kọ Alleluya. 2. Si Ọ, ifẹ ẹni t'o wa, Ninu Majẹmu Ọlọrun, A ń kọ Alleluya. 3. Si Ọ ohun ẹni ti ń pe, Asako kuro ninu ẹsẹ, A ń kọ Alleluya. 4. Si Ọ, agbara ẹni ti, O ń wẹ'ni mo, t'o ń wo'ni san, A ń kọ Alleluya. 5. Si Ọ ododo Ẹni ti, Gbogbo ileri Rẹ jẹ tiwa, A ń kọ Alleluya. 6. Si Ọ, Olukọ at'Ọrẹ, Amọna wa titi d'opin, A ń kọ Alleluya. 7. Si Ọ, Ẹni ti Kristi ran, f Ade oun gbogbo ẹbun Rẹ, A ń kọ Alleluya. 8. f Si Ọ, Ẹni t'o jẹ ọkan, Pẹlu Baba ati Ọmọ, A ń kọ Alleluya. AMIN
Hymn 156 – SI O Olutunu orun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia