Hymn 155 – EYIN Olukore 'nu oko | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "EYIN Olukore 'nu oko" (C&S Hymn #155, Yoruba). 1. ẸYIN Olukore 'nu oko, T'o rọ t'o si ń daku, Ẹ wa duro de Olugbala,…
1. ẸYIN Olukore 'nu oko, T'o rọ t'o si ń daku, Ẹ wa duro de Olugbala, Yio sọ agbara wa d'ọtun. Awọn to duro d'Oluwa, Y'o tun agbara wọn se, Wọn o fi iyẹ fo bi idi, Wọn o sare wọn ki yio daku (2ce) Wọn o rin ki yio rẹ wọn (2ce) Wọn o sare wọn ki yio daku, Arẹ ki yio mu wọn. 2. Idaku at'arẹ 'gbakugba, N mu wa lati ma kun, B'a ba mo p'Olugbala wa mbẹ, Eese ti yoo fi re wa? 3. Ẹ yọ fun pe O mba wa gbe pọ, Ani titi d'opin, W'oke fi 'gboya tẹsiwaju, Y'o ran 'ranwọ Rẹ si wa. AMIN
Hymn 155 – EYIN Olukore 'nu oko | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia