Hymn 149 – KERUBU ati Serafu | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "KERUBU ati Serafu" (C&S Hymn #149, Yoruba). 1. KÉRÚBÙ ati Séráfù, Ẹ k'afojuba Olori, Ayọ loni yi jẹ fun wa, Awa Ijọ…

Hymn 149 – KERUBU ati Serafu | C&S Yoruba Hymnary
1. KÉRÚBÙ ati Séráfù, Ẹ k'afojuba Olori, Ayọ loni yi jẹ fun wa, Awa Ijọ Séráfù. Awa ń jo o, awa ń yọ, Awa si ń yọ, Fun ẹmi t'o ri ẹmi, Halleluyah, Halleluyah, S'Ọlọrun Mẹtalọkan. 2. Ijọ Kérúbù ẹ mura, Lati fi 'yin fun Baba, K'Ọlọrun ran Olori lọwọ, K'o le ko wa de Kenaan. 3. Ẹyin ẹgbẹ Igbimọ wa, At'Ijọ Aladura, Ẹ ku afojuba loni, Fun ore nla Ọlọrun. 4. A dupẹ lọwọ Ọlọrun, T'o mu yin lọ, t'o mu yin bọ, Ẹ f'ogo fun Olugbala! T'o jẹ ki ẹmi ri ẹmi. 5. Jọwọ loni yi Oluwa, F'Ẹmi Mimọ ba wa gbe; Pe nigbẹyin k'a le pẹlu, Awọn Kérúbù t'ọrun. 6. K'a gb'ọwọ lọwọ ara wa, Ẹ ku abọ ẹ ku'le; Gbogbo wa ni yoo gb'ere naa, L'agbara Mẹtalọkan. 7. Isẹ pọ ti awa o se, Fun Baba Mimọ loke, Ẹyin ọm'ẹgbẹ Akọrin, Ẹ mura lati jagun. 8. A ki Olori Ijọ wa, Pẹlu awọn ọm'ogun rẹ, Pe ẹ ku isẹ ẹmi yi, K'ade ogo jẹ ti wa. Ka jọ ho o, K‘a jọ yọ, Halleluya, K‘a jọ f‘iyin fun Baba, Halleluyah, Halleluyah, Ogo, iyin fun Baba.

Hymn 149 – KERUBU ati Serafu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia