Hymn 148 – ENI T'O Ba gbo 'kede oro naa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "ENI T'O Ba gbo 'kede oro naa" (C&S Hymn #148, Yoruba). 1. ẸNI T'O Ba gbọ 'kede ọrọ naa, Wasu ihinrere fun gbogbo ayé,…
1. ẸNI T'O Ba gbọ 'kede ọrọ naa, Wasu ihinrere fun gbogbo ayé, Tan ihinrere naa nibi gbogbo, Ẹni t'o ba fẹ le wa. Egbe: Ẹni t'o ba fẹ (2ce) Kede ihinrere naa jakejado, Pe Baba ń pe awọn asako wa 'le, Ẹni t'o ba fẹ le wa. 2. Ẹni t'o ba mbọ ko gbọdọ l'ọra, 'Lẹkun si silẹ wọle nisinsin yii, Jesu nikan l'ọna iye otọ, Ẹni t'o ba fẹ le wa. 3. Ileri naa wa fun awọn to fẹ, Ẹni t'o ba fẹ y'o f'oriti d'opin, Ẹni t'o ba fẹ iye ni titi lai, Ẹni t'o ba fẹ le wa. 4. Séráfù, Kérúbù, kede ọrọ naa, Wi fun gbogbo ayé pe Jesu mbọ wa, Si gba iye awọn to ba fẹ la Ẹni t'o ba fẹ le wa. 5. Ọpọ ni oungbẹ iye ń gbẹ sibẹ, Awọn diẹ si ti di ominira, Mura lati f'ọrọ naa bọ otosi, Ki wọn ba le ri 'ye gba. 6. Lala isẹ pọ, ere si daju, Ade ti ki sa y'o jẹ tiyin titi, A o ma tan b'orun niwaju itẹ, T'ẹ ba sisẹ naa d'opin. AMIN
Hymn 148 – ENI T'O Ba gbo 'kede oro naa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia