Hymn 127 – A F'OPE f'Olorun t'O da wa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "A F'OPE f'Olorun t'O da wa" (C&S Hymn #127, Yoruba). 1. A F'ỌPẸ f'Ọlọrun t'O da wa, Ti O n bọ t'O si n sikẹ wa, Oun ni…
1. A F'ỌPẸ f'Ọlọrun t'O da wa, Ti O n bọ t'O si n sikẹ wa, Oun ni Oluwa ti o le bukun wa, Ẹ jẹ k'a jọ kọrin s'Ẹlẹda wa. 2. A dupẹ f'ọna t'o pe wa si, Sinu ọkọ 'gbala kẹhin, Ran wa lọwọ k'a le fi iwa wa jọ, Awọn Ijọ mimọ Seraf' t'oke. 3. A dupẹ fun okun ilera, Ti o n fi fun awa ọmọ Rẹ. Ẹyin l'Ọlọrun ti ko jẹ ko rẹ wa, A dupẹ a yin O Olore wa. 4. A dupẹ pe o n gbadura wa, Ni ọna gbogbo t'a n pe Ọ si, Papa nigba ti esu n fẹ tafa rẹ, Ẹ ke Halleluyah s'Olusẹgun. 5. A dupẹ f'alafia ara, T'o n fun wa, t'o si n jẹ k'a mọ Ọ, Pe 'wọ l'Ọlọrun t'o le s'ohun gbogbo, A dupẹ a yin Ọba Olore. 6. A dupẹ f'Ẹmi t'o n dari wa, 'Gbat' awa ọmọ Rẹ n fẹ sako, Oun n f'ohun kẹlẹ pe wa pada s'agbo, Mẹtalọkan Mimọ a juba Rẹ. 7. A dupẹ p'a mọ ojubọ Rẹ, Larin hilahilo ayé yi, O n jẹ k'a mọ pe Iwọ ni Baba wa, Ayọ, ayọ, ayọ, ani Baba. 8. Ọpẹ l'o yẹ Olodumare, Fun didasi ti O ń da wa si, T'O ń bọ t'O si ń sikẹ wa lojojumọ, Ọpẹ, ọpẹ, iyin f'Olore wa. 9. A dupẹ fun Ọ, Ẹlẹda wa, Fun isẹ Rẹ t'O ń se larin wa, Ti O ko fi wa silẹ ni'sẹju kan, Ogo, Ọla, Iyin s'Ẹlẹda wa. 10. Ọlọrun Ẹlẹda Séráfù, Ti aginju ayé wa yi, Gb'ohun wa k'o si ma lo nigba gbogbo, K'a le b'awọn Seraf' t'ọrun kọrin. 11. Baba wa jọwọ k'o gb'ọpẹ wa, Larin Ijọ mimọ Séráfù, Ohun ọpẹ ni k'O ma fi s'arin wa, Titi a o fi de 'le Paradise. AMIN
Hymn 127 – A F'OPE f'Olorun t'O da wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia