Hymn 126 – OLORUN ailopin iwo | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLORUN ailopin iwo" (C&S Hymn #126, Yoruba). 1. ỌLỌRUN ailopin, Iwọ, L'a f'iyin atọkan wa fun, Gbogbo 'sẹ Rẹ l'ayé yin…

Hymn 126 – OLORUN ailopin iwo | C&S Yoruba Hymnary
1. ỌLỌRUN ailopin, Iwọ, L'a f'iyin atọkan wa fun, Gbogbo 'sẹ Rẹ l'ayé yin Ọ, A juba Rẹ, Oluwa wa; Baba ayérayé, jẹ ki, Ọkan wa wolẹ n'itẹ Rẹ. 2. Awọn angẹl' n kọrin yin Ọ, Balogun, Ọba 'wọn Ọba, Kikan l'awọn Kérúbù n yin, Seraf' si yin Mẹtalọkan; Wọn n kọ, Mimọ, mimọ, mimọ, Ọrun, ayé, kun f'ogo Rẹ! 3. Ọlọrun awọn baba wa, Awọn Woli ti royin Rẹ, Ẹgbẹ Aposteli rere, Wọn mbẹ l'ayọ ati ogo; Woli ati awọn mimọ Dapọ lati gb'ọla Rẹ ga. 4. Olor' awọn ajẹriku, Wọn n f'otọ sogo ninu Rẹ, Ijọ gbe ohun rẹ soke, Yin Ẹlẹda gbogbo ayé; Wọn si mba 'wọn t'o y'itẹ ka, Kọrin in 'jinlẹ Mẹtalọkan. 5. Baba, Ọlọla ailopin, Tirẹ l'agbara at' ifẹ, A juba ọmọ Rẹ ọwọn, T'O mbẹ n'nu ogo pẹlu; At'Ọlọrun Ẹmi Mimọ , Olutunu ayérayé. AMIN

Hymn 126 – OLORUN ailopin iwo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia