Hymn 104 – Ogo fun Eleda Mimo l'oke | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Ogo fun Eleda Mimo l'oke" (C&S Hymn #104, Yoruba). 1. Ogo fun Ẹlẹda Mimọ l'oke, Ẹni t'o gba wa lọwọ iparun To si fi…
1. Ogo fun Ẹlẹda Mimọ l'oke, Ẹni t'o gba wa lọwọ iparun To si fi ẹsẹ wa le ọna iye, Ọpẹ fun Kristi Mimọ. Ẹ f'iyin fun Baba Mimọ l'oke, Ẹni ti o da wa si di oni, Lati yọ ayọ ajọdun oni, Ti Ijọ Mimọ Seraf. 2. A dupẹ fun Baba Olore wa, Ẹni ti o san gbogbo gbese wa, Lati inu iku s'iye ailopin, Ogo fun Kristi Mimọ. 3. B'emi ko tilẹ ni ọrọ ayé, Sugbọn mo mọ pe Kristi wa fun mi, Lọnakọna yoo pese fun mi, Ogo f'Olugbala. 4. B'ẹsẹ mi tilẹ pọn bi ododo, Kristi Oluwa ki yoo ta mi nu, Sibẹ yoo fi'fẹ fa mi mọra, Halleluya si Kristi mi. 5. Kinla! Iwọ ẹni irapada? Iwọ yoo ha siyemeji bi? Iwọ sa gbẹkẹle Oluwa rẹ, Baba wa yoo pese. 6. Ẹ s'ọpẹ fun Mẹtalọkan Mimọ, Ẹni ti o n se ọgbọn ayérayé, Ẹ fi iyin fun Mẹtalọkan Mimọ, Ogo f'Ẹlẹda wa. AMIN
Hymn 104 – Ogo fun Eleda Mimo l'oke | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia