Hymn 103 – Oluwa l'Olus'aguntan mi | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "Oluwa l'Olus'aguntan mi" (C&S Hymn #103, Yoruba). 1. Oluwa l'Olus'aguntan mi, Emi k'o salaini, O mu mi dubulẹ 'nu papa…

Hymn 103 – Oluwa l'Olus'aguntan mi | C&S Yoruba Hymnary
1. Oluwa l'Olus'aguntan mi, Emi k'o salaini, O mu mi dubulẹ 'nu papa oko, Tutu minimini. Awa dupẹ, at' ọpẹ da, Fun idasi Rẹ fun wa, Larin Ijọ Séráfù. 2. O mu mi lọ si iha omi, Idakẹ rọrọ si de, O si tu ọkan mi lara, Ni ipa orukọ Rẹ. 3. Ni tootọ bi mo tilẹ ń rin, Larin afonifoji, Emi ki yoo bẹru ibi kan, Nitori o wa pẹlu mi. 4. Ogo Rẹ ati ọpa Rẹ, Wọn si n tu mi ninu, Iwọ tẹ tabili ounjẹ silẹ, Ni iwaju mi. 5. Ni tootọ ire ati anu, Ni yoo ma tọ mi lehin, Emi o gbẹkẹle Oluwa, Ni gbogbo ọjọ ayé mi. 6. K'a f'ogo fun Baba wa loke, K'a f'ogo fun Ọmọ Rẹ, K'a fogo fun Ẹmi Mimọ, Mẹtalọkan l'ọpẹ yẹ Awa dupẹ, at'ọpẹ da, Fun idasi Rẹ fun wa, Larin Ijọ Séráfù. AMIN

Hymn 103 – Oluwa l'Olus'aguntan mi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia