Hymn xlv – Olorun mi saanu fun mi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Olorun mi saanu fun mi" (C&S Hymn #xlv, Yoruba). ALL: Ọlọrun mi saanu fun mi Gẹgẹ bi 'seun Ifẹ Rẹ Gẹgẹ bi irọnu anu Rẹ…
ALL: Ọlọrun mi saanu fun mi Gẹgẹ bi 'seun Ifẹ Rẹ Gẹgẹ bi irọnu anu Rẹ Nu 'rekoja mi kuro. CHR: Dariji mi, Dariji mi ) Kemi le sisẹ Rẹ dopin ) 2ce LEAD: Wẹ mi ni awẹmọ kuro Ninu gbogbo aisedede F'ẹjẹ Kalfari Rẹ wẹ mi N o funfun ju ẹgbọn owu CHR: Dariji mi, Dariji mi ) Kemi le sisẹ Rẹ dopin ) 2ce LEAD: Daya titun si'nu mi Gbe agbara Ẹmi wọ mi Ki n le kọrin irapada Kahọn mi le yin Ọ logo. CHR: Dariji mi, Dariji mi ) Kemi le sisẹ Rẹ dopin ) 2ce LEAD: Iwọ ko bere ẹbọ ẹsẹ Sugbọn 'robinujẹ ọkan Mo fi Irẹlẹ tẹriba Nibi pẹpẹ Rẹ gbọrẹ mi. CHR:- Dariji mi, Dariji mi ) Kemi le sisẹ Rẹ dopin ) 2ce
Hymn xlv – Olorun mi saanu fun mi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia