Hymn 938 – MASE beru ‘wo okan mi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "MASE beru ‘wo okan mi" (C&S Hymn #938, Yoruba). 1. MASE beru ‘wo okan mi Eleda mi ni nma foya Oluwa pe mi l’oruko O…
1. MASE beru ‘wo okan mi Eleda mi ni nma foya Oluwa pe mi l’oruko O ndabobo, ko si jinna Eje Re ti s‘etu fun mi O nfe, O si nto mi sibe. 2. ‘Gba mo nkoja larin ibu Mo f’igbagbo toro 'ranwo Igbi si duro l’okere Won bi kuro Ii ori mi Emi ko beru ipa won Ko si ewu, Olorun mbe. 3. Mo yi oju igbagbo s’i Mo ntesiwaju larin ‘na Ina gbagbe lati jo mi Owo ina njo yi mi ka Mo jewo agbar’ami na Mo ke pe" Temi ni Jesu. 4. Olugbala, duro ti mi Dabobo mi nigba ‘danwo Pa mi mo ni ikawo Re F’agbara ‘gbala han n’nu mi Ki apa Re je abo mi Ko s'ohun le ja mi kuro. 5. B'O si ti pe mi pe ki nwa Wo Olore ti ngba ni la Un o rin lori okun ti nja Igbi yo gbe ese mi ro Nki yo beru isan na Bi o ti wu ki o le to. 6. Gbat‘okunkun b’oju orun T’igbi ‘banuje yi mi ka T‘iji ibinu ru soke To fere bori okan mi Emi mi yo ri dake je Y’o gb‘ohun jeje pe, 'simi. 7. Bi mo wa n‘nu eru ‘ponju Laisewu un o sete iku B’ese doju ija ko mi Ti esu gbe ogun ti mi B’igbo Mose, un o ma gberu Ina ki o pa mi lara. Amin
Hymn 938 – MASE beru ‘wo okan mi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia