Hymn 934 – ONA Re, Oluwa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "ONA Re, Oluwa" (C&S Hymn #934, Yoruba). 1. ONA Re, Oluwa B’o ti wu ko ha to! Fi owo Re to mi Yan ipa mi fun mi. 2. B’o…
1. ONA Re, Oluwa B’o ti wu ko ha to! Fi owo Re to mi Yan ipa mi fun mi. 2. B’o rorun b’o soro Daradara lo je B’o wo, b’o to tara Lodo Re l’opin si. 3. Nko gbodo yan ‘pin mi Nko tile je yan an Yan fun mi Olorun Ki mba le rin dede. 4. Ijoba ti mo nwa Tire ni, jek‘ ona T’o re ‘be je Tire Bi beko un o sina. 5. Gba ago mi, f’ayo Tab’ibanuje kun B’o ti to l’oju Re Yan ‘re tab’ibi mi. 6. Yiyan ki se temi Ninu ohunkohun Iwo s’Oluto mi Ogbon, ohun gbogbo. Amin
Hymn 934 – ONA Re, Oluwa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia