Hymn 931 – EMI ogbon, to oju wa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "EMI ogbon, to oju wa" (C&S Hymn #931, Yoruba). 1. EMI ogbon, to oju wa Kuro ninu asan aye S’oto on ‘fe orun Emi oye ti…
1. EMI ogbon, to oju wa Kuro ninu asan aye S’oto on ‘fe orun Emi oye ti o daju Fi mole orun fun wa Lati wa nkan toke. 2. Emi ‘moran s’Amona wa F’ijakadi aye ko wa K’a gba ade t’orun Emi ‘gboya, k’agbara Re Ran wa lowo nigba ‘danwo Pa wa mo lailese. 3. Emi imo, to ese wa Li ona Re ti ko l’ewu T’awon angel ‘ti rin Nib i t’Iwo Oluto wa Iwo Emi ifokansin Mu wa sunm’Olorun. 4. Sunmo wa lojo aye wa Emi iberu Olorun N’ikoko aya wa F‘owo t’o ye kun okan wa Lati sin ife mimo Re T'o l'ododo julo. 5. Ma to wa lo l'alafia Sinu iye ainipekun K'a jere giga na K’a ja ogun aye wa yi Nipa agbara Re mimo K'a si ba Krist'joba. Amin
Hymn 931 – EMI ogbon, to oju wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia