Hymn 929 – JESU nikan ni a nwasu | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "JESU nikan ni a nwasu" (C&S Hymn #929, Yoruba). 1. JESU nikan ni a nwasu Jesu nikan l’a n rohin Awa yoo gbe Jesu soke…

Hymn 929 – JESU nikan ni a nwasu | C&S Yoruba Hymnary
1. JESU nikan ni a nwasu Jesu nikan l’a n rohin Awa yoo gbe Jesu soke Oun nikan l‘awa n fe ri. Egbe: Jesu nikan Jesu nikan Jesu nikan l’orin wa Olugbala, Oluwosan Oba ti n bo leekeji. 2. Jesu ni Olugbala wa, O ru gbogbo ebi wa Ododo Re l‘O gbe wo wa O n s' agbara wa d’otun. Egbe: Jesu nikan... 3. Jesu l’o n so wa di mimo T'o n we abawon wa nu O n segun ese at’ara Nipa iranwo Emi. Egbe: Jesu nikan... 4. Jesu ni Oluwosan wa O ti ru ailera wa Nip’agbara ajinde Re A ni ilera pipe. Egbe: Jesu nikan... 5. Jesu nikan l’agbara wa Agbara Pentikosti Joo, da agbara yii iu wa F’Emi Mimo Re kun wa. Egbe: Jesu nikan... 6. Jesu ni awa n duro de A n reti ohun ipe ‘Gba t'O ba de Jesu nikan Yoo je orin wa titi. Egbe: Jesu nikan Jesu nikan Jesu nikan l’orin wa Olugbala, Oluwosan Oba ti n bo leekeji. Amin

Hymn 929 – JESU nikan ni a nwasu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia