Hymn 909 – Gba t’a b’Oluwa rin | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "Gba t’a b’Oluwa rin" (C&S Hymn #909, Yoruba). 1. Gba t’a b’Oluwa rin N’nu ‘mole Oro re Ona wa yoo ti ni ‘mole to Gba…

Hymn 909 – Gba t’a b’Oluwa rin | C&S Yoruba Hymnary
1. Gba t’a b’Oluwa rin N’nu ‘mole Oro re Ona wa yoo ti ni ‘mole to Gba t’a ba n se ‘fe Re Oun yoo maa ba wa gbe Ati awon t‘o gbekele won le e Egbe: Sa gekele e Ona miiran ko si Lati l'ayo n'nu Jesu Ju pe k'a gbeke le. 2. Ko s‘ohun t’o le de L’oke tabi n‘ile T’o le ko agbara Re l‘oju Iyemeji, eru Ibanuje, ekun Ko le duro b’a ba gbekele e. Egbe: Sa gekele e... 3. Ko si wahala mo Tabi ibanuje O ti san gbogbo ‘gbese wonyi Ko si arokan mo Tabi ifajuro Sugbon ‘bukun b’a bagbekele e. Egbe: Sa gekele e... 4. A ko le f’enu so B’ife Re ti po to Titi a o fi f’ara wa rubo Aanu ti o n fi han At’ayo t’O n fun ni Je ti awon ti o gbekele e. Egbe: Sa gekele e... 5. N’idapo pelu Re A o jokoo l’ese re Tabi ki a maa rin pelu Re Awa yoo gbo ti Re A o j’ise t'O ran wa Ma beru, sa gbekele e nikan. Egbe: Sa gekele e Ona miiran ko si Lati l'ayo n'nu Jesu Ju pe k'a gbeke le. Amin

Hymn 909 – Gba t’a b’Oluwa rin | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia