Hymn xxvii – Ni kutukutu a de o — a de o | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Ni kutukutu a de o — a de o" (C&S Hymn #xxvii, Yoruba). Ni kutukutu a de o — a de o, Aji pọn omi kutukutu owurọ, Ki…
Ni kutukutu a de o — a de o, Aji pọn omi kutukutu owurọ, Ki pọn omi riru, A wa kanlẹkun — a tẹwọ adura, Baba jẹ ko yẹ wa. Ire olokun ni ba olokun, ) Ire ọlọsa ni ba ọlọsa )2ce Edumare Baba — Wa sure fun wa. Ibukun owo la n tọrọ, Eledumare wa fifun wa, Awa kanlẹkun a tẹwọ adura, Baba jẹ ko yẹ wa. Ibukun Ọla la n tọrọ — Eledumare Ibukun Ọla la n tọrọ — Eledumare, Ibukun Ọmọ la n tọrọ — Eledumare Alafia la n tọrọ — Eledumare Agbara ẹmi la n tọrọ — Eledumare A wa kanlẹkun — a tẹwọ adura, Baba jẹ ko yẹ wa, Ni kutukutu a de o — a de o, Aji pọn omi kutukutu owurọ, Kii pọn omi riru, A wa kanlẹkun — a tẹwọ adura, Baba jẹ ko yẹ wa.
Hymn xxvii – Ni kutukutu a de o — a de o | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia