Hymn 881 – KO su wa lati ma ko orinti igbani | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "KO su wa lati ma ko orinti igbani" (C&S Hymn #881, Yoruba). 1. KO su wa lati ma ko orinti igbani Ogo f'Olorun Aleluya!…

Hymn 881 – KO su wa lati ma ko orinti igbani | C&S Yoruba Hymnary
1. KO su wa lati ma ko orinti igbani Ogo f'Olorun Aleluya! A le fi igbagbo korin na s'oke kikan Ogo f’Olorun, Aleluya! Egbe: Omo Olorun ni eto lati ma bu s'ayo Pe ona yi nye wa si Okan wa ns'aferi Re: Nigb’o se a o de afin Oba wa ologo Ogo f'Olorun, Aleluya! 2. Awa mbe n'nu ibu ife t'o ra wa pada Ogo f'Olorun Aleluya! Awa y'o fi iye goke lo s‘oke orun Ogo f‘Olorun, Aleluya! Egbe: Omo Olorun ni eto... 3. Awa nlo si afin kan ti a fi wura ko Ogo f’Olorun Aleluya! Nibiti ao ri Oba ogo n’nu ewa Re Ogo f’Olorun, Aleluya! Egbe: Omo Olorun ni eto... 4. Nibe ao korin titun t’anu t‘O da wa nde Ogo f’Olorun Aleluya! Nibe awon ayanfe yo korin ‘yin ti Krist; Ogo f’Olorun, Aleluya! Egbe: Omo Olorun ni eto lati ma bu s'ayo Pe ona yi nye wa si Okan wa ns'aferi Re: Nigb’o se a o de afin Oba wa ologo Ogo f'Olorun, Aleluya! Amin

Hymn 881 – KO su wa lati ma ko orinti igbani | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia