Hymn 856 – A KU odun a ku yedun | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "A KU odun a ku yedun" (C&S Hymn #856, Yoruba). A KU ọdun a ku yedun, Awa onigbagbọ, Ọdun de a yọ fori awa ku orire,…

Hymn 856 – A KU odun a ku yedun | C&S Yoruba Hymnary
A KU ọdun a ku yedun, Awa onigbagbọ, Ọdun de a yọ fori awa ku orire, Olodumare lo se eyi fun wa Ayọ ayọ ni tawa Ka ma jo, ka si ma yọ, Awa onigbagbọ a ku ori re A ku ọdun o, A ku iyedun o, Awa onigbagbọ K'Olodumare ko wa pẹlu wa, Aseyi sa mọdun. Ko si ku ko si banujẹ, Iye Iye ni tiwa, Baba ti nu omije wa Ẹrin Ẹrin ni tiwa, Niwọn ta ba ti gbẹkẹle, Baba ọrun, Ko si bẹru fun wa mọ, O ti da wa loju wi pé, A ko ni pofo lọjọ ayé wa. A ku ọdun o, A ku iyedun o, Awa onigbagbọ K'Olodumare ko wa pẹlu wa, Aseyi sa mọdun. Ọdọdun ni ẹwa n wa, Gbogbo wa yo samọdun , Awa mbẹ Jah Jehofa ko fi re kari wa, Ka ma se ri banujẹ ati ofo, Ninu ọdun to mbọ wa, Ni agbara Baba Ọrun, A o samọdun pẹl' alafia. A ku ọdun o, A ku iyedun o, Awa onigbagbọ K'Olodumare ko wa pẹlu wa, Aseyi sa mọdun. AMIN A ku ọdun o, A ku iyedun o, Awa onigbagbọ K'Olodumare ko wa pẹlu wa, Aseyi sa mọdun.

Hymn 856 – A KU odun a ku yedun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia