Hymn 842 – OJO oni lo tan | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OJO oni lo tan" (C&S Hymn #842, Yoruba). ỌJỌ oni lọ tan, Oru sunmọle, Okunkun si de tan, Ilẹ si ti su. Okunkun bo ilẹ,…

Hymn 842 – OJO oni lo tan | C&S Yoruba Hymnary
ỌJỌ oni lọ tan, Oru sunmọle, Okunkun si de tan, Ilẹ si ti su. Okunkun bo ilẹ, Awọn 'rawọn yọ, Ẹranko at' ẹyẹ, Lọ si 'busun wọn. Jesu, f'orun didun, F'ẹni alarẹ, Jẹ ki ibukun Rẹ, Pa oju mi de Jẹ k'ọmọ kekere, La ala rere; S'ọlọkọ t'ewu n wu, Ni oju omi. Ma tọju alaisan, Ti ko r'orun sun; Awọn ti n ro ibi; Jọ da wọn l'ẹkun. Ninu gbogbo oru, Jẹ k'Angeli Rẹ, Mase olusọ mi, L'ori ẹni mi. 'Gba t'ilẹ ba si mọ, Jẹ k'emi dide; B'ọmọ ti ko l'ẹsẹ, Ni iwaju Rẹ. Ogo ni fun Baba, Ati fun Ọmọ, Ati f'Ẹmi Mimọ , Lai ati lailai. AMIN

Hymn 842 – OJO oni lo tan | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia