Hymn 839 – OJU ko ti ri, eti ko ti gbo | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OJU ko ti ri, eti ko ti gbo" (C&S Hymn #839, Yoruba). OJU ko ti ri, eti ko ti gbọ, Ẹsẹ t'Olùgbàlà pa f'eniyan Rẹ, Awọn…

Hymn 839 – OJU ko ti ri, eti ko ti gbo | C&S Yoruba Hymnary
OJU ko ti ri, eti ko ti gbọ, Ẹsẹ t'Olùgbàlà pa f'eniyan Rẹ, Awọn ti o fẹran ti wọn fẹran Rẹ, Ti wọn n fi ayọ sin ninu ile Rẹ. B'Ọrun ti dun to ko s'ẹni le mọ, Ayọ rẹ ko ti la s'ọkan ẹda, Bi ijọba ayé ba lewa to yi, Bawo n'ijọba Ọlọrun yoo ti rẹ? Ilu ail'ẹsẹ ti ko si iku, Nibi ti a kii pe ―O digbose‖ Ti ko si ipinya ti ko si ẹkun, Ibi ti Jesu jọba yoo ti layọ to. Ipade pẹlu awọn to ti lọ, Baba t'oun t'ọmọ ọkọ t'oun t'aya, Ọrẹ at'ojulumọ t'o ti saju, A! b'ijọba Ọlọrun yoo ti dun to. Pẹlu awọn mimọ lati ma kọ, Orin Mose ati t'Ọd'aguntan, Nibi ti ko si aniyan fun ara, Ti Jesu gbe n sikẹ wa yoo ti dun to. Ki n padanu ayé oun ọrọ rẹ, K'ẹsẹ mi le tẹ ilu ogo yi, Nigba mo ba n rin ita wura l'oke, N ó gbagbe gbogbo iya ti mo ti jẹ. AMIN

Hymn 839 – OJU ko ti ri, eti ko ti gbo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia