Hymn 837 – JESU fe mi, mo mo be | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "JESU fe mi, mo mo be" (C&S Hymn #837, Yoruba). JESU fẹ mi, mo mọ bẹ, Bibeli l'o sọ fun mi; Tirẹ l'awọn ọmọde, Wọn ko…
JESU fẹ mi, mo mọ bẹ, Bibeli l'o sọ fun mi; Tirẹ l'awọn ọmọde, Wọn ko lagbara, Oun ni. Jesu fẹ mi Ẹn' t'o ku, Lati si ọrun silẹ; Yoo wẹ ẹsẹ mi nu; Jẹ ki ọmọ Rẹ wọle. Jesu fẹ mi sibẹ si, Bi emi tilẹ s'aisan, Lor' akete aisan mi, Y'o t'itẹ Rẹ wa sọ mi. Jesu fẹ mi, y'o duro, Ti mi ni gbogb' ọna mi, 'Gba mba f'ayé yi silẹ, Y'o mu mi re 'le ọrun. AMIN
Hymn 837 – JESU fe mi, mo mo be | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia