Hymn 830 – MO fe ki n dabi Jesu | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "MO fe ki n dabi Jesu" (C&S Hymn #830, Yoruba). MO fẹ ki n dabi Jesu, Ninu iwa pẹlẹ; Ko s'ẹni t'o gbọrọ 'binu, Lẹnu Rẹ…
MO fẹ ki n dabi Jesu, Ninu iwa pẹlẹ; Ko s'ẹni t'o gbọrọ 'binu, Lẹnu Rẹ lẹkan ri. Mo fẹ ki n dabi Jesu, L'adura 'gba gbogbo, L'ori oke ni Oun nikan, Lọ pade Baba Rẹ Mo fẹ ki n dabi Jesu, Emi ko ri ka pe, Bi wọn ti korira Rẹ to, O s'ẹnikan n'ibi. Mo fẹ ki n dabi Jesu, Ninu isẹ rere; K'a le wi nipa temi pe, O se 'wọn t'o le se. Mo fẹ ki n dabi Jesu, T'o f'iyọnu wi pé, Jẹ k'ọmọde wa sọdọ Mi‖, Mo fẹ jẹ ipe Rẹ. Sugbọn n ko dabi Jesu, O si han gbangba bẹ; Jesu fun mi l'ore-ọfẹ, Se mi ki n dabi Rẹ. AMIN
Hymn 830 – MO fe ki n dabi Jesu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia