Hymn 777 – JESU Olori Egbe wa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "JESU Olori Egbe wa" (C&S Hymn #777, Yoruba). JESU Olori Ẹgbẹ wa, Bukun wa k'awa to lọ; Baba Olorisun gbogbo, Jẹ ka ri…
JESU Olori Ẹgbẹ wa, Bukun wa k'awa to lọ; Baba Olorisun gbogbo, Jẹ ka ri Ọ larin wa. Jah Jehovah! Jah Jehovah! Kabiyesi Ọba wa (6 times) Jọwọ Jesu awa mbẹ Ọ, K'a ma ri agbako ayé; Ka ri'se, k'ọja k'o ta, K'ọmọ Rẹ ma rahun mọ. Jah Jehovah! Jah Jehovah! Kabiyesi Ọba wa (6 times) Sure fun wa l'ọjọ ayé wa, K'ebi alẹ ma pa wa; K'ẹnikẹni mase rahun; M'ẹsẹ Ẹgbẹ wa duro. Jah Jehovah! Jah Jehovah! Kabiyesi Ọba wa (6 times) Ma jẹ ki fitila Rẹ ku, Larin Ẹgbẹ Séráfù; Gẹgẹ bi Séráfù t'ọrun, Ki gbogbo wa jọ yin Ọ. Jah Jehovah! Jah Jehovah! Kabiyesi Ọba wa (6 times) Rant' ẹgbẹ t'o wa l'okere, Fun wọn l'okun ilera; Ajẹ, oso ko ma ri wọn, Iwọ lo n s'Alabo wọn. Jah Jehovah! Jah Jehovah! Kabiyesi Ọba wa (6 times) Jehovah Jireh Ọba wa, Jehovah Nissi Baba, Jehovah Shalom, S'amọna wa lọjọ 'ku. Jah Jehovah! Jah Jehovah! Kabiyesi Ọba wa (6 times) AMIN Jah Jehovah! Jah Jehovah! Kabiyesi Ọba wa (6 times)
Hymn 777 – JESU Olori Egbe wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia