Hymn 773 – OLORUN, awa fe | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OLORUN, awa fe" (C&S Hymn #773, Yoruba). ỌLỌRUN, awa fẹ, Ile t'ọla Rẹ wa; Ayọ ibugbe Rẹ, Ju gbogbo ayọ lọ. Ile adura…
ỌLỌRUN, awa fẹ, Ile t'ọla Rẹ wa; Ayọ ibugbe Rẹ, Ju gbogbo ayọ lọ. Ile adura ni, Fun awa ọmọ Rẹ; Jesu, O wa nibẹ, Lati gbọ ẹbẹ wa. Awa fẹ asẹ Rẹ, Ki 'o dun to layé; Nib' awọn olotọ, N ri Ọ nitosi wọn. Awa fẹ ọrọ Rẹ Ọrọ Alafia; Titunu at'iye; Ọrọ ayọ titi. A fẹ kọrin anu, T'a n ri gba l'ayé yi, Sugbọn awa fẹ mọ, Orin ayọ t'ọrun. Jesu, Oluwa wa, Busi 'fẹ wa nihin; Mu wa de 'nu ogo, Lati yin Ọ titi. AMIN
Hymn 773 – OLORUN, awa fe | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia