Hymn 750 – O SUN, ni Jesu wi, | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "O SUN, ni Jesu wi," (C&S Hymn #750, Yoruba). O SUN, ni Jesu wi, Nigba ti Lasaru, Ẹni t'o ku, ti a ti sin, T'a ti tẹ…
O SUN, ni Jesu wi, Nigba ti Lasaru, Ẹni t'o ku, ti a ti sin, T'a ti tẹ s'iboji. Oku ọjọ mẹrin, Sun ni, loju Jesu; Oun l'Ajinde ati Iye, Fun awọn t'o gbagbọ. Ọrẹ Jesu ki ku, Wọn a ma parada, Kuro ni kokoro ilẹ, S'ohun ti n fo l'oke di Sun, ara, olufẹ, Jesu duro ti ọ, Ma foya, o ti seleri, Ajinde f'ẹni Re. O fẹrẹ gb'ohun na, Lat' oju orun rẹ, Ohun didun Jesu ti y'o Pe o si ajinde. A ko ni barajẹ, Bi alainireti, O d'owurọ l'a o ki o, Sunre Sun re. Awa pẹlu y'o sun, Ni akoko tiwa; A! k'ilẹ mọ ba gbogbo wa, L'ẹsẹ Olugbala. AMIN
Hymn 750 – O SUN, ni Jesu wi, | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia