Hymn 745 – NINU Egbe Mimo yi, ti Mose gbe kale | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "NINU Egbe Mimo yi, ti Mose gbe kale" (C&S Hymn #745, Yoruba). NINU Ẹgbẹ Mimọ yi, ti Mose gbe kalẹ, L'Oluwa s'awọn Tirẹ…

Hymn 745 – NINU Egbe Mimo yi, ti Mose gbe kale | C&S Yoruba Hymnary
NINU Ẹgbẹ Mimọ yi, ti Mose gbe kalẹ, L'Oluwa s'awọn Tirẹ ni ayanfẹ, Arayé le ma kẹgan, arayé le ma sata, Sugbọn Séráfù mọ ẹni ti wọn n sin. Ẹgbẹ na, ẹgbẹ na, Ta fi ran Mose, Orimọlade, Ta fi ifẹ se 'pilẹ, K'ẹnikẹni fẹsẹ le, K'ibukun ayérayé le jẹ tiwa. O yan Baba 'ladura lati j'Olurọpo rẹ, Nigba ti ipe de lati mu re 'le O yan awọn Aposteli lati gberin ẹgbẹ na, Ki wọn mura lati tan 'hin na kalẹ. Ẹgbẹ na, ẹgbẹ na, Ta fi ran Mose, Orimọlade, Ta fi ifẹ se 'pilẹ, K'ẹnikẹni fẹsẹ le, K'ibukun ayérayé le jẹ tiwa. Bi wọn ti jẹ oloye ki wọn jẹ onirẹlẹ, Lati tẹle 'pasẹ Jesu Oluwa; Ka le se wọn l'asepe bi Aposteli 'gbani, Ti adura wọn jẹ amu-bi-ina . Ẹgbẹ na, ẹgbẹ na, Ta fi ran Mose, Orimọlade, Ta fi ifẹ se 'pilẹ, K'ẹnikẹni fẹsẹ le, K'ibukun ayérayé le jẹ tiwa. Adura ti Mose gba fun awọn Aposteli, Mọ wọn lori lọjọ na titi d'oni; Wọn ti jẹ ẹni 'bukun, Emi Mi ko ba wọn gbe. 'Tori na ni wọn se wa ni aisubu Ẹgbẹ na, ẹgbẹ na, Ta fi ran Mose, Orimọlade, Ta fi ifẹ se 'pilẹ, K'ẹnikẹni fẹsẹ le, K'ibukun ayérayé le jẹ tiwa. Gbogbo obinrin oloye, Mary, Martha, Esther, Ni eto ẹyin oloye mẹtẹta; Ẹ mura giri s'isẹ bi awọn ti igbani, Wọn ko ya awọn Aposteli lẹsẹ kan. Ẹgbẹ na, ẹgbẹ na, Ta fi ran Mose, Orimọlade, Ta fi ifẹ se 'pilẹ, K'ẹnikẹni fẹsẹ le, K'ibukun ayérayé le jẹ tiwa. Ẹ wo 'we kekere na ti Mose gbe kalẹ, Bibeli ọrọ Ọlọrun la pe 'we na, Ẹnikẹni to tẹle ọrọ iyebiye rẹ, Yio n' ipo kikun lagbara Oluwa. Iwe na, iwe na, Eti rẹ to ti ja yi lo fi n wu ni, Sugbọn oun na lo tọka gbogbo Kristiani si iye F'ẹnikẹni to sisẹ rẹ lai 'lẹru. Ki ore- ọfẹ Jesu Kristi wa lori papọ, Ko si ma ba wa gbe lai ati lailai, Mary, Martha, Esta, 'ti Baba nla mejila, F'Ogo Ọlọrun han, ọmọ 'gun igbala. Ko si ma, bukun wa, Ninu ona mimọ na ti a wa yi, Ka le jogun igbala. Lẹhin ayé titun ni, Lodo Jesu Oluwa ka ma sogo. AMIN Ko si ma, bukun wa, Ninu ona mimọ na ti a wa yi, Ka le jogun igbala. Lẹhin ayé titun ni, Lodo Jesu Oluwa ka ma sogo.

Hymn 745 – NINU Egbe Mimo yi, ti Mose gbe kale | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia