Hymn 743 – KERUBU ati Serafu | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "KERUBU ati Serafu" (C&S Hymn #743, Yoruba). KÉRÚBÙ ati Séráfù, Wọn n yi'tẹ Baba ka, Nigbakugba niwaju Rẹ, Ni wọn n…

Hymn 743 – KERUBU ati Serafu | C&S Yoruba Hymnary
KÉRÚBÙ ati Séráfù, Wọn n yi'tẹ Baba ka, Nigbakugba niwaju Rẹ, Ni wọn n kọrin ogo. N kọrin Ogo, Ogo, Ogo, (2). Gbogb' Ọmọ Ẹgbẹ Kérúbù, Ẹ tọju iwa yin; Gbogbo Ẹgbẹ t'o wa l'ayé, Ni 'dapọ mọ t'ọrun. N kọrin Ogo, Ogo, Ogo, (2). Gbogb' Ọmọ Ẹgbẹ Séráfù, Ẹ tọju iwa yin; K'a ba le pẹl' awọn t'ọrun, Lati ma juba Rẹ. N kọrin Ogo, Ogo, Ogo, (2). Awọn ẹgbẹ t'o wa l'orun, Wọn wo bi a ti n ja; Wọn si n fi ohun kan wi pé, Ẹ ma tẹ siwaju. N kọrin Ogo, Ogo, Ogo, (2). Ninu ipọnju at'ẹgun, Ninu 'rukerudo; Ninu irumi at'iji, Yoo s'ọna wa fefe. N kọrin Ogo, Ogo, Ogo, (2). Majẹmu ati ẹjẹ rẹ, Ni igbẹkẹle wa; B' ileri na tilẹ falẹ, Sugbọn ko le pẹ de. N kọrin Ogo, Ogo, Ogo, (2). Nigba t'a ba par' isẹ wa, Ni ayé osi yi; Ade Ogo yoo jẹ tiwa, T'ẹnikan ko le gba. N kọrin Ogo, Ogo, Ogo, (2). Ogo, ọla at'agbara, Ni fun Mẹtalọkan, Ayérayé Ọlọrun wa, Amin, bẹni ki o ri. N kọrin Ogo, Ogo, Ogo, (2). AMIN N kọrin Ogo, Ogo, Ogo, (2).

Hymn 743 – KERUBU ati Serafu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia