Hymn 737 – GBOGBO aye Serafu de | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "GBOGBO aye Serafu de" (C&S Hymn #737, Yoruba). GBOGBO ayé Séráfù de, Lati kede ọrọ naa, T'Olugbala ti fi lelẹ, Lọwọ…
GBOGBO ayé Séráfù de, Lati kede ọrọ naa, T'Olugbala ti fi lelẹ, Lọwọ Orimolade. Lọdọ Baba Aladura, Ẹni to d'ẹgbẹ yi silẹ, Nibi Séráfù, Kérúbù Yin Baba Mimọ logo. Adahunse, atẹyẹpẹ, Aye Ẹgbẹ si silẹ, K'ẹyin wa ronupiwada, Lọdọ Orimolade, Lọdọ Baba Aladura, Ẹni to d'ẹgbẹ yi silẹ, Nibi Séráfù, Kérúbù Yin Baba Mimọ logo. Babalawo, onitira, Ẹ wa ronupiwada; Kẹ wa di opo iye Rẹ mu, Lọdọ Orimọlade. Lọdọ Baba Aladura, Ẹni to d'ẹgbẹ yi silẹ, Nibi Séráfù, Kérúbù Yin Baba Mimọ logo. Sanpọnna ko lọ sọra rẹ, Lọdọ Ẹgbẹ Séráfù; Oniwunde ti sọkalẹ, Sinu Ẹgbẹ Kérúbù. Lọdọ Baba Aladura, Ẹni to d'ẹgbẹ yi silẹ, Nibi Séráfù, Kérúbù Yin Baba Mimọ logo. Egungun ati gẹlẹdẹ, Ẹ wa ronupiwada, Ka jumọ yin Ọlọrun wa, Ninu Ẹgbẹ Séráfù. Lọdọ Baba Aladura, Ẹni to d'ẹgbẹ yi silẹ, Nibi Séráfù, Kérúbù Yin Baba Mimọ logo. Igunnu ati agẹmọ, Ẹ wa ronupiwada; K'ẹ wa di opo iye mu, Lọdọ Orimọlade. Lọdọ Baba Aladura, Ẹni to d'ẹgbẹ yi silẹ, Nibi Séráfù, Kérúbù Yin Baba Mimọ logo. A juba Ọlọrun Baba, Ọmọ at' Ẹmi Mimọ, Mẹtalọkan ayérayé, Ninu Ẹgbẹ Séráfù Lọdọ Baba Aladura, Ẹni to d'ẹgbẹ yi silẹ, Nibi Séráfù, Kérúbù Yin Baba Mimọ logo. Kérúbù ati Séráfù, T'o wa ni gbogbo ayé; K'awa damure wa giri, Lati kede ọrọ na. Lọdọ Baba Aladura, Ẹni to d'ẹgbẹ yi silẹ, Nibi Séráfù, Kérúbù Yin Baba Mimọ logo. A ki Baba Aladura, T'Ọlọrun f'Ẹgbẹ yi ran; Jerusalemu sọkalẹ; Lọdọ Orimolade. Lọdọ Baba Aladura, Ẹni to d'ẹgbẹ yi silẹ, Nibi Séráfù, Kérúbù Yin Baba Mimọ logo. Ẹyin ara, ẹ ku 'duro, Ẹyin ara, ẹ ku 'joko, Ọkọ 'gbala wa lode Eko, Lọdọ Orimọlade Lọdọ Baba Aladura, Ẹni to d'ẹgbẹ yi silẹ, Nibi Séráfù, Kérúbù Yin Baba Mimọ logo. Ọlọrun to gbọ t'Elijah, T'o si mu lọ sọdọ Rẹ; Ko wa ran Mose lọwọ, Ko le ko wa d'ọdọ Rẹ. Lọdọ Baba Aladura, Ẹni to d'ẹgbẹ yi silẹ, Nibi Séráfù, Kérúbù Yin Baba Mimọ logo. Ọlọrun Abraham, Isaac ati Jakobu, Baba, Ọmọ, Ẹmi Mimọ , Mẹtalọkan ayérayé. Lọdọ Baba Aladura, Ẹni to d'ẹgbẹ yi silẹ, Nibi Séráfù, Kérúbù Yin Baba Mimọ logo. Adaba ọrun, sọkalẹ, Ẹ wa ran Baba lọwọ, K'ade ogo le jẹ tirẹ, Ti ẹnikan…
Hymn 737 – GBOGBO aye Serafu de | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia