Hymn 725 – EYIN Egbe Serafu o | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "EYIN Egbe Serafu o" (C&S Hymn #725, Yoruba). ẸYIN Ẹgbẹ Séráfù o, Ẹ ma foya a a, Ẹ ma foya Jesu yoo wa pẹlu wa o, Ẹ ma…
ẸYIN Ẹgbẹ Séráfù o, Ẹ ma foya a a, Ẹ ma foya Jesu yoo wa pẹlu wa o, Ẹ ma foya a a , Ẹ ma foya, O ti seleri fun wa, Awi mayẹhun ni Baba, Ẹ ma foya a o, Ẹ ma foya. Fogo Ọlọrun han kun f'ayọ, Ẹ ma foya a a, Ẹ ma foya, Ifẹloju ẹ bu sayọ, Ẹ ma foya a a, Ẹ ma foya. O ti seleri fun wa, Awi mayẹhun ni Baba, Ẹ ma foya a o, Ẹ ma foya. Baba yoo pese fun wa o, Ẹ ma foya a a, Ẹ ma foya, O ti mọ gbogbo ẹdun wa, Ẹ ma foya a a, Ẹ ma foya. O ti seleri fun wa, Awi mayẹhun ni Baba, Ẹ ma foya a o, Ẹ ma foya. Ẹ jẹ ka damure wa o, Ẹ ma foya a a, Ẹ ma foya, Lati se isẹ wa d'opin, Ẹ ma foya a a, Ẹ ma foya. O ti seleri fun wa, Awi mayẹhun ni Baba, Ẹ ma foya a o, Ẹ ma foya. Ẹgbẹ Mary ti yege o, Ẹ ma foya a a, Ẹ ma foya, Awọn 'Ya ni Isreali, Ẹ ma foya a a, Ẹ ma foya, O ti seleri fun wa, Awi mayẹhun ni Baba, Ẹ ma foya a o, Ẹ ma foya. Ọm' ogun Kristi ko mura, Ẹ ma foya a a, Ẹ ma foya, Ki Dafidi ko damure, Ẹ ma foya a a, Ẹ ma foya, O ti seleri fun wa, Awi mayẹhun ni Baba, Ẹ ma foya a o, Ẹ ma foya. Ẹyin Agbagba a ki yin o, Ẹ ma foya a a, Ẹ ma foya, Isẹ 'le yi ti pari o, Ẹ ma foya a o. O ti seleri fun wa, Awi mayẹhun ni Baba, Ẹ ma foya a o, Ẹ ma foya. AMIN O ti seleri fun wa, Awi mayẹhun ni Baba, Ẹ ma foya a o, Ẹ ma foya.
Hymn 725 – EYIN Egbe Serafu o | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia