Hymn 704 – ALAFIA ni f'Egbe na | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "ALAFIA ni f'Egbe na" (C&S Hymn #704, Yoruba). ALAFIA ni f'Ẹgbẹ na, T'o n se ajọdun loni, Kérúbù t'oke sọkalẹ, Lati ba…

Hymn 704 – ALAFIA ni f'Egbe na | C&S Yoruba Hymnary
ALAFIA ni f'Ẹgbẹ na, T'o n se ajọdun loni, Kérúbù t'oke sọkalẹ, Lati ba wa yọ ayọ na. Awa n jo -- awa n yọ ) Ogun ọrun sọkalẹ )2ce Ọmọ Ẹgbẹ Kristi Mimọ, Ẹ wa k'a jọ y'ayọ na, K'ẹnikẹni ma ku sẹyin, Gbogbo wa ni Jesu n pe. Awa n jo -- awa n yọ ) Ogun ọrun sọkalẹ )2ce Ẹgbẹ Kérúbù Séráfù, At'awọn aladura, At'ẹyin onisin-owurọ, Jẹ k'a kọrin na soke. Awa n jo -- awa n yọ ) Ogun ọrun sọkalẹ )2ce Ẹgbẹ Mary, Ẹgbẹ Martha, Ẹgbẹ Ayaba Esther, Ẹgbẹ Dorcas gbohun soke, K'a jumọ yọ ayọ na., Awa n jo -- awa n yọ ) Ogun ọrun sọkalẹ )2ce Orin Halle, Halleluyah, L'awa yoo ma kọ lorun, Gba t'a ba ri Olugbala, Lor' itẹ Baba loke. Awa n jo -- awa n yọ ) Ogun ọrun sọkalẹ )2ce Ẹgbẹ Dafidi: Ẹgbẹ Aaroni, Ẹgbẹ F'Ogo Ọlọrun han, Ẹgbẹ Baba nla mejila, Gbe'da 'sẹgun yin soke. Awa n jo -- awa n yọ ) Ogun ọrun sọkalẹ )2ce Ẹ f'Ogo fun Baba loke Ẹ f'Ogo fun Ọmọ Rẹ, Ogo ni fun Ẹmi Mimọ, Ọpe yẹ Mẹtalọkan. Awa n jo awa n yọ ) Ogun ọrun sọkalẹ )2ce AMIN Awa n jo awa n yọ ) Ogun ọrun sọkalẹ )2ce

Hymn 704 – ALAFIA ni f'Egbe na | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia