Hymn 660 – IYAWO ti Isaaki gbe | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "IYAWO ti Isaaki gbe" (C&S Hymn #660, Yoruba). IYAWO ti Isaaki gbe, Pẹlu Rebeka aya rẹ, Ọlọrun f'ibukun fun wọn, Gẹgẹ…
IYAWO ti Isaaki gbe, Pẹlu Rebeka aya rẹ, Ọlọrun f'ibukun fun wọn, Gẹgẹ b'igbeyawo Adam. Ẹ yọ, mo si tun wi pé e yọ (2) Ẹ yọ, ẹ yo, ẹ yọ nin' Oluwa ẹ yọ. Bẹni ko ri fun yin loni, Arakunrin, Arabinrin, K'ayọ ọrun kun ọkan yin, Pẹlu 'bukun atoke wa. Ẹ yọ, mo si tun wi pé e yọ (2) Ẹ yọ, ẹ yo, ẹ yọ nin' Oluwa ẹ yọ. Ninu idamu ayé yi, Oluwa p'awọn tirẹ mọ; Fi wọn si abẹ isọ Rẹ, Ki wọn le bọ lọwọ ewu. Ẹ yọ, mo si tun wi pé e yọ (2) Ẹ yọ, ẹ yo, ẹ yọ nin' Oluwa ẹ yọ. Ẹyin ọrẹ, at'ibatan, K'Oluwa gbọ adura yin, K'O f'ibukun fun yin pẹlu, L'ọkunrin ati l'obinrin. Ẹ yọ, mo si tun wi pé e yọ (2) Ẹ yọ, ẹ yo, ẹ yọ nin' Oluwa ẹ yọ. Ẹyin ọm'Ẹgbẹ Séráfù, Ati ọm'Ẹgbẹ Kérúbù, Ọjọ ayọ ni eyi jẹ, K'Oluwa jẹ ki ire kari, Ẹ yọ, mo si tun wi pé e yọ (2) Ẹ yọ, ẹ yo, ẹ yọ nin' Oluwa ẹ yọ. A f'Ogo f'Ọlọrun Baba, A f'Ogo f'Ọlọrun Ọmọ, A f'Ogo fun Ẹmi Mimọ ; Mẹtalọkan Mimọ lailai. Ẹ yọ, mo si tun wi pé e yọ (2) Ẹ yọ, ẹ yo, ẹ yọ nin' Oluwa ẹ yọ. AMIN Ẹ yọ, mo si tun wi pé e yọ (2) Ẹ yọ, ẹ yo, ẹ yọ nin' Oluwa ẹ yọ.
Hymn 660 – IYAWO ti Isaaki gbe | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia