Hymn 653 – ATUPA 'wa n jo gere, aso wa funfun lau | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "ATUPA 'wa n jo gere, aso wa funfun lau" (C&S Hymn #653, Yoruba). ATUPA 'wa n jo gere, asọ wa funfun lau, A n duro…
ATUPA 'wa n jo gere, asọ wa funfun lau, A n duro d'ọkọ 'yawo, a ha le wọle bi? A mọ pe a ko ni nkan t'a le pe ni tiwa, Ina, ororo, at'asọ, t'owo Rẹ nikan wa, Ẹ wo Ọkọ 'yawo mbọ, gbogbo wa le wọle, T'atupa wa n jo gere! t'asọ wa funfun lau. mf Ẹ jade lọ pade Rẹ, 'lẹkun ti si silẹ, Ogo t'o tan loju Rẹ mu gbogbo ọna mọlẹ, Gba ipe lati wọle, o j'ohun gbogbo lọ, Ma jafara! gb'atupa Rẹ! w'ayọ ayérayé. Ẹ wo Ọkọ 'yawo mbọ, gbogbo wa le wọle, T'atupa wa n jo gere! t'asọ wa funfun lau. Arẹwa 'gbeyawo na, b'ilẹkun si sibẹ, A mọ p'awọn t'o wọle d'ẹni 'bukun lailai, A si ri pe Ọ wa ni ju ẹnikẹni lọ Sugbọn b'ilẹkun ti, 'lẹkun ki yoo tun si mo lai. Ẹ wo Ọkọ 'yawo mbọ, gbogbo wa le wọle, T'atupa wa n jo gere! t'asọ wa funfun lau. AMIN Ẹ wo Ọkọ 'yawo mbọ, gbogbo wa le wọle, T'atupa wa n jo gere! t'asọ wa funfun lau.
Hymn 653 – ATUPA 'wa n jo gere, aso wa funfun lau | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia