Hymn 651 – OJO ko, ase na leyi | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OJO ko, ase na leyi" (C&S Hymn #651, Yoruba). ỌJỌ ko, ase na leyi, Mo f'ara mi fun yin; Ẹ wo, mo f'ẹjẹ mi fun yin Lati…

Hymn 651 – OJO ko, ase na leyi | C&S Yoruba Hymnary
ỌJỌ ko, ase na leyi, Mo f'ara mi fun yin; Ẹ wo, mo f'ẹjẹ mi fun yin Lati ran yin pada. O di 'nu 'jọba Baba Mi, Ki n to tun 'ba yin mu, 'Gbana ẹkun ko ni si mọ, A o ma yọ titi. Titi l'a o ma jẹ Ounjẹ yi, K'o to di igba na; Ka gbogb' ayé l'ọpọlọpọ, Y'o ma jẹ, y'o ma mu. 'Bukun atọrunwa y'o ma Wa lor' awọn t'o n jẹ; N ó gbe or'-itẹ Baba mi, Ma pes'-aye fun wọn. p Sugbọn nisinsin yi, ago Kikoro l'em' o mu, Emi o mu nitori yin, Ago 'rora iku. Ẹ ko le mọ 'banujẹ Mi, Ẹ ko ti r'ogo Mi; Sugbọn ẹ ma s'eyi titi, K'ẹ ma fi ranti Mi. AMIN

Hymn 651 – OJO ko, ase na leyi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia