Hymn 645 – 'LEKUN kan mbe t'o sipaya | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "'LEKUN kan mbe t'o sipaya" (C&S Hymn #645, Yoruba). 'LẸKUN kan mbẹ t'o sipaya, Lati inu ọna rẹ wa ; 'Mọlẹ lat'ori…

Hymn 645 – 'LEKUN kan mbe t'o sipaya | C&S Yoruba Hymnary
'LẸKUN kan mbẹ t'o sipaya, Lati inu ọna rẹ wa ; 'Mọlẹ lat'ori agbelebu, N f'Ifẹ Olugbala han. A Anu jinlẹ o le jẹ, Pe 'lẹkun na si silẹ fun mi Fun mi? Fun mi? Pe o si silẹ fun mi. 'Lẹkun na si silẹ lọfẹ, Fun gbogbo ẹni n fẹ igbala, F'ọlọrọ ati talaka, Fun gbogbo orilẹ-ede, A Anu jinlẹ o le jẹ, Pe 'lẹkun na si silẹ fun mi Fun mi? Fun mi? Pe o si silẹ fun mi. Tẹ siwaju b'ọta n rojọ, Gbati 'lẹkun na si silẹ; Gb' agbelebu jere ade, Anu Ifẹ ailopin A Anu jinlẹ o le jẹ, Pe 'lẹkun na si silẹ fun mi Fun mi? Fun mi? Pe o si silẹ fun mi. 'Gba ba d'oke odo lọhun, A o gb'agbelebu silẹ; A o bẹrẹ gb'ade iye, A o fẹ Jesu si i l'ọrun. A Anu jinlẹ o le jẹ, Pe 'lẹkun na si silẹ fun mi Fun mi? Fun mi? Pe o si silẹ fun mi. AMIN A Anu jinlẹ o le jẹ, Pe 'lẹkun na si silẹ fun mi Fun mi? Fun mi? Pe o si silẹ fun mi.

Hymn 645 – 'LEKUN kan mbe t'o sipaya | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia