Hymn 643 – KI NI y'o kehin aye | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "KI NI y'o kehin aye" (C&S Hymn #643, Yoruba). KI NI y'o kẹhin ayé? Kérúbù pẹlu Séráfù, Gẹgẹ bi ọkọ Noah, Kérúbù pẹlu…
KI NI y'o kẹhin ayé? Kérúbù pẹlu Séráfù, Gẹgẹ bi ọkọ Noah, Kérúbù pẹlu Séráfù, Ọlọrun Elijah, T'o k'awọn eniyan rẹ, L'aginju ayé ja, Kérúbù pẹlu Séráfù. Irawọ gbogbo wa n tan, Kérúbù pẹlu Séráfù, Ẹgbẹ mimọ wo l'eyi? Kérúbù pẹlu Séráfù, Ọlọrun Kérúbù, T'o k'awọn eniyan rẹ, L'aginju ayé ja, Kérúbù pẹlu Séráfù. Gbọ, wọn n kọ Halleluya! Kérúbù pẹlu Séráfù, Orin iyin s'Ọba wa, Kérúbù pẹlu Séráfù Ọlọrun Séráfù, T'o k'awọn eniyan rẹ, L'aginju ayé ja, Kérúbù pẹlu Séráfù. Gbọ, Ẹda ọrun n kọrin, Kérúbù pẹlu Séráfù; Ẹda ayé ko gberin, Kérúbù pẹlu Séráfù, A gboju wa soke, S'Ọlọrun Alaye, Gb'adura ẹdun wa, Kérúbù pẹlu Séráfù. Mimọ, Mimọ l'Ọlọrun, Kérúbù pẹlu Séráfù Ọlọrun Mẹtalọkan, Kérúbù pẹlu Séráfù, Ọlọrun Abraham, Ọlọrun Isaaki, Ọlọrun Jakobu, Kérúbù pẹlu Séráfù. Ogo f'Ọlọrun Baba, Kérúbù pẹlu Séráfù, Ogo f'Ọlọrun Ọmọ, Kérúbù pẹlu Séráfù: Ogo f'Ẹmi Mimọ , Mẹtalọkan lailai, T'o dẹgbẹ yi silẹ, Kérúbù pẹlu Séráfù. AMIN
Hymn 643 – KI NI y'o kehin aye | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia