Hymn 618 – EYI l'ase nla Jehofa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "EYI l'ase nla Jehofa" (C&S Hymn #618, Yoruba). EYI l'asẹ nla Jehofa Yoo wa titi lai; Ẹlẹsẹ b'Iwọ at'emi, K'a tun…
EYI l'asẹ nla Jehofa Yoo wa titi lai; Ẹlẹsẹ b'Iwọ at'emi, K'a tun gbogbo wa bi. Okunkun y'o jẹ ipa wa B'a wa ninu ẹsẹ; A ki o ri ijọba Rẹ, Bi a ko d'atunbi. Bi baptisi wa jẹ 'gbarun, Asan ni gbogbo rẹ, Eyi ko le w'ẹsẹ nu, Bi a ko tun wa bi. Wo ise 'were ti a n se, Ko ni iranwọ Rẹ, Wọn ko s'ọkan wa di ọtun B'awa ko d'atunbi. Lọ kuro ninu ẹsẹ rẹ, Ja ẹwọn Esu nu; Gba Kristi gbọ tọkantọkan, Iwọ o d'atunbi. AMIN
Hymn 618 – EYI l'ase nla Jehofa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia