Hymn 616 – JESU n lo sinu odo Jordan | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "JESU n lo sinu odo Jordan" (C&S Hymn #616, Yoruba). JESU n lọ sinu odo Jordan, (3) Lọdọ John Baptist. A n lọ sodo…

Hymn 616 – JESU n lo sinu odo Jordan | C&S Yoruba Hymnary
JESU n lọ sinu odo Jordan, (3) Lọdọ John Baptist. A n lọ sodo Jordan, Pẹlu Olugbala wa; A n lọ sodo Jordan! Odo iwẹnumọ. Ka to le d'ade, a o ma kọrin, (3) Orin ifẹ mimọ A n lọ sodo Jordan, Pẹlu Olugbala wa; A n lọ sodo Jordan! Odo iwẹnumọ. Jesu yoo gbade f'ọmọ Rẹ, (3) F'awọn ayanfẹ Rẹ A n lọ sodo Jordan, Pẹlu Olugbala wa; A n lọ sodo Jordan! Odo iwẹnumọ. Adaba, mimọ sọkalẹ (3) S'or' Olugbala wa A n lọ sodo Jordan, Pẹlu Olugbala wa; A n lọ sodo Jordan! Odo iwẹnumọ. A gbohun kan lat'ọrun wa, (3) Eyi l'ayanfẹ Mi. A n lọ sodo Jordan, Pẹlu Olugbala wa; A n lọ sodo Jordan! Odo iwẹnumọ. Ẹ ma gbọ Tirẹ titi ayé, (3) Ayé ainipẹkun. A n lọ sodo Jordan, Pẹlu Olugbala wa; A n lọ sodo Jordan! Odo iwẹnumọ. Jesu Oluwa ti d'odo na, (3) Odo Iwẹnumọ. A n lọ sodo Jordan, Pẹlu Olugbala wa; A n lọ sodo Jordan! Odo iwẹnumọ. Gbogbo ẹlẹsẹ, ẹ wa kalọ, (3) Sinu odo Jordan. A n lọ sodo Jordan, Pẹlu Olugbala wa; A n lọ sodo Jordan! Odo iwẹnumọ. Kerub' Seraf' ẹ wa ka lọ (3) Sọd' Olugbala wa. A n lọ sodo Jordan, Pẹlu Olugbala wa; A n lọ sodo Jordan! Odo iwẹnumọ. Ade iye yoo jẹ ti wa (3) Bi a ba gba Jesu gbọ. A n lọ sodo Jordan, Pẹlu Olugbala wa; A n lọ sodo Jordan! Odo iwẹnumọ. AMIN A n lọ sodo Jordan, Pẹlu Olugbala wa; A n lọ sodo Jordan! Odo iwẹnumọ.

Hymn 616 – JESU n lo sinu odo Jordan | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia