Hymn 588 – A O SISE! A o sisE! om' Olorun ni wa | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "A O SISE! A o sisE! om' Olorun ni wa" (C&S Hymn #588, Yoruba). A O SISẸ! A o sisẹ! ọm' Ọlọrun ni wa, Jẹ k'a tẹle ipa…

Hymn 588 – A O SISE! A o sisE! om' Olorun ni wa | C&S Yoruba Hymnary
A O SISẸ! A o sisẹ! ọm' Ọlọrun ni wa, Jẹ k'a tẹle ipa ti Oluwa wa to; K'a f'imọran Rẹ sọ agbara wa d'ọtun, K'a fi gbogbo okun wa sisẹ t'a o se. Foriti! Foriti! Ma reti, ma sọna, Titi Oluwa o fi de. A o sisẹ! A o sisẹ! Bọ awọn t'ebi npa, Ko awọn alarẹ lọ s'orisun iye! Ninu agbelebu l'awa o ma sogo; Gbati a ba n kede pe, ―ọfẹ n'Igbala.‘ Foriti! Foriti! Ma reti, ma sọna, Titi Oluwa o fi de. A o sisẹ, a o sisẹ! gbogbo wa ni y'o se, Ijọba okunkun at'irọ yo fọ, A o si gbe orukọ Jesu leke, N'nu orin iyin wa pe, ―ọfẹ n'Igbala. Foriti! Foriti! Ma reti, ma sọna, Titi Oluwa o fi de. A o sisẹ! A o sisẹ! l'agbara Oluwa, Agbala at'ade y'o si jẹ ere wa; 'Gbat' ile awọn olotọ ba di tiwa, Gbogbo wa o jọ ho pe, ―ọfẹ n'Igbala. Foriti! Foriti! Ma reti, ma sọna, Titi Oluwa o fi de. AMIN Foriti! Foriti! Ma reti, ma sọna, Titi Oluwa o fi de.

Hymn 588 – A O SISE! A o sisE! om' Olorun ni wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia