Hymn 561 – MA tọju wa Baba Orun | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "MA tọju wa Baba Orun" (C&S Hymn #561, Yoruba). MA tọju wa Baba Ọrun, Larin 'damu ayé yi, Pa wa mọ k'o si ma bọ wa, A…

Hymn 561 – MA tọju wa Baba Orun | C&S Yoruba Hymnary
MA tọju wa Baba Ọrun, Larin 'damu ayé yi, Pa wa mọ k'o si ma bọ wa, A ko n' iranwọ miran; Sugbọn gbogbo 'bukun l'a ni, B'Ọlọrun jẹ Baba wa. Olugbala, dariji wa, Iwọ sa m'ailera wa; 'Wọ ti rin ayé saaju wa, 'Wọ ti mọ 'se inu rẹ; B' ẹn' ikanu at' alarẹ, L'O ti la 'ginju yi ja. L'O ti la 'ginju yi ja. Ẹmi Ọlọrun, sọkalẹ, F'ayọ ọrun k'ọkan wa, K'ifẹ dapọ mọ iya wa, At'adun ti ki su ni, B'a ba pese fun wa bayi, Ki l'o le mu sinmi wa? AMIN

Hymn 561 – MA tọju wa Baba Orun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia