Hymn 536 – WO! b'o ti dun to lati ri | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "WO! b'o ti dun to lati ri" (C&S Hymn #536, Yoruba). WO! b'o ti dun to lati ri, Awọn ara t'o rẹ; Ara ti ọkan wọn…

Hymn 536 – WO! b'o ti dun to lati ri | C&S Yoruba Hymnary
WO! b'o ti dun to lati ri, Awọn ara t'o rẹ; Ara ti ọkan wọn s'ọkan, L'ẹgbẹ idẹ mimọ. 'Gba isan 'fẹ t'ọdọ Krist sun, O san s'ọkan gbogbo; Alafia Olodumare, Dabobo gbogbo rẹ. O dabi ororo didun, Ni irugbọn Aaron; Kikan rẹ m'asọ rẹ run 're, O san s'agbada rẹ. O dara b'iri owurọ, T'o n sẹ soke Sion, Nibit' Ọlọrun f'ogo han, T'o m' ore-ọfẹ han. AMIN

Hymn 536 – WO! b'o ti dun to lati ri | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia