Hymn 522 – JESU Olugbala, Oba mi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "JESU Olugbala, Oba mi" (C&S Hymn #522, Yoruba). JESU Olugbala, Ọba mi, Gbohun mi nigba ti mo n pe, Gbohun mi lati…
JESU Olugbala, Ọba mi, Gbohun mi nigba ti mo n pe, Gbohun mi lati 'bugbe Rẹ, Rọjo ore-ọfẹ silẹ. Oluwa mi, mo fẹran Rẹ, Jẹ ki n le ma fẹran Rẹ si. Jesu, mo ti jafara ju, N ó se le fẹ Ọ b'o ti yẹ, Em'o se le gb'ogo Rẹ ga, Ati ẹwa orukọ Rẹ. Oluwa mi, mo fẹran Rẹ, Jẹ ki n le ma fẹran Rẹ si. Jesu, kil'o ri ninu mi, Ti 'fẹ na fi pọ to bayi? Ore Rẹ si mi ti pọ to! O ta gbogbo ero mi yọ! Oluwa mi, mo fẹran Rẹ, Jẹ ki n le ma fẹran Rẹ si. Jesu, 'Wọ o jẹ orin mi, Tirẹ l'aya at'ọkan mi: Tirẹ ni gbogbo ini mi; Olugbala, 'Wọ ni temi: Oluwa mi, mo fẹran Rẹ, Jẹ ki n le ma fẹran Rẹ si. AMIN Oluwa mi, mo fẹran Rẹ, Jẹ ki n le ma fẹran Rẹ si.
Hymn 522 – JESU Olugbala, Oba mi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia